Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 12:12-18 BIBELI MIMỌ (BM)

12. ati fún àwọn ọ̀mọ̀lé, ati àwọn agbẹ́kùúta. Ninu rẹ̀, wọn yóo ra igi ati òkúta tí wọn yóo lò fún àtúnṣe náà ati láti san owó gbogbo ohun tí wọ́n nílò fún àtúnṣe ilé OLUWA.

13. Wọn kò lò lára owó náà láti fi ra agbada fadaka, abọ́, fèrè, tabi àwọn ohun èlò wúrà tabi ti fadaka sí ilé OLUWA,

14. ṣugbọn wọn ń lò ó láti fi san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ ati láti ra àwọn ohun èlò fún àtúnṣe ilé OLUWA.

15. Wọn kò sì bèèrè àkọsílẹ̀ iye tí àwọn tí wọn ń ṣàkóso iṣẹ́ náà ná nítorí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́.

16. Ṣugbọn wọn kò da owó ìtanràn ati owó ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀ mọ́ owó fún àtúnṣe ilé OLUWA, nítorí pé àwọn alufaa ni wọ́n ni owó ìtanràn ati ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

17. Ní àkókò náà, Hasaeli, ọba Siria gbógun ti ìlú Gati, ó sì ṣẹgun rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó dojú kọ Jerusalẹmu,

18. Joaṣi, ọba Juda, kó gbogbo àwọn ẹ̀bùn mímọ́ tí Jehoṣafati ati Jehoramu ati Ahasaya, àwọn baba ńlá rẹ̀ tí wọ́n ti jọba ṣáájú rẹ̀ yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ati èyí tí òun pàápàá ti yà sọ́tọ̀ ati gbogbo wúrà tí ó wà ninu àwọn ilé ìṣúra ilé OLUWA ati èyí tí ó wà ní ààfin, ó fi wọ́n ranṣẹ sí Hasaeli, ọba Siria. Hasaeli bá kó ogun rẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 12