Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 10:31-36 BIBELI MIMỌ (BM)

31. Ṣugbọn Jehu kò kíyèsára kí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀lé Òfin OLUWA Ọlọrun Israẹli; ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu tí ó mú kí Israẹli hù ni ó tẹ̀lé.

32. Ní àkókò náà ni OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí dín ilẹ̀ Israẹli kù. Hasaeli ọba Siria gba gbogbo àwọn agbègbè Israẹli,

33. láti ìhà ìlà oòrùn Jọdani, gbogbo ilẹ̀ Gileadi ati ti ẹ̀yà Gadi, ẹ̀yà Reubẹni ati ẹya Manase. Láti Aroeri tí ó wà ní àfonífojì Arinoni tíí ṣe ilẹ̀ Gileadi ati ilẹ̀ Baṣani.

34. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehu ṣe, ati bí ó ti lágbára tó, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

35. Jehu kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sí Samaria, Jehoahasi ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

36. Gbogbo àkókò tí Jehu fi jọba lórí Israẹli ní Samaria jẹ́ ọdún mejidinlọgbọn.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 10