Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 10:26-30 BIBELI MIMỌ (BM)

26. wọ́n kó gbogbo àwọn ère tí wọ́n wà níbẹ̀ jáde, wọ́n sì sun wọ́n níná.

27. Wọ́n wó àwọn ère ati ilé ìsìn Baali lulẹ̀, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ilé ìgbẹ́ títí di òní yìí.

28. Bẹ́ẹ̀ ni Jehu ṣe pa ìsìn Baali run ní Israẹli.

29. Ṣugbọn Jehu tẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú kí Israẹli bọ ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù, tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ó wà ní Bẹtẹli ati Dani.

30. OLUWA sọ fún Jehu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí o ti ṣe èyí tí ó dára lójú mi, o ti ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe sí ilé Ahabu, tí o ṣe ohun tí ó wà lọ́kàn mi, àwọn ọmọ rẹ, títí dé ìran kẹrin, yóo máa jọba ní Israẹli.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 10