Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 1:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn ikú Ahabu ọba, àwọn ará Moabu ṣọ̀tẹ̀ sí Israẹli, wọ́n fẹ́ fi tipátipá gba òmìnira.

2. Ahasaya ọba ṣubú láti orí òkè ilé rẹ̀ ní Samaria, ó sì farapa pupọ. Nítorí náà ni ó ṣe rán oníṣẹ́ lọ bèèrè lọ́wọ́ Baalisebubu, oriṣa Ekironi, bóyá òun yóo sàn ninu àìsàn náà tabi òun kò ní sàn.

3. Ṣugbọn angẹli OLUWA kan pàṣẹ fún wolii Elija, ará Tiṣibe pé, “Lọ pàdé àwọn oníṣẹ́ ọba Samaria, kí o sì bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli ni ẹ fi ń lọ wádìí nǹkan lọ́dọ̀ Baalisebubu, oriṣa Ekironi?’

4. Ẹ lọ sọ fún ọba pé, báyìí ni OLUWA wí, ‘O kò ní sàn ninu àìsàn náà, kíkú ni o óo kú.’ ”Elija sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 1