Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 6:17-29 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Gideoni tún dáhùn, ó ní, “Bí inú rẹ bá yọ́ sí mi, fi àmì kan hàn mí pé ìwọ OLUWA ni ò ń bá mi sọ̀rọ̀.

18. Jọ̀wọ́, má kúrò níhìn-ín títí tí n óo fi mú ẹ̀bùn mi dé, tí n óo sì gbé e kalẹ̀ níwájú rẹ.”Angẹli náà dá Gideoni lóhùn, ó ní, “N óo dúró títí tí o óo fi pada dé.”

19. Gideoni bá wọlé lọ, ó tọ́jú ọmọ ewúrẹ́ kan, ó sì fi ìyẹ̀fun ìwọ̀n efa kan ṣe burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu. Ó kó ẹran tí ó sè sinu agbọ̀n kan, ó da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sinu ìkòkò kan, ó gbé e tọ Angẹli OLUWA náà lọ ní abẹ́ igi Oaku, ó sì gbé wọn kalẹ̀ níwájú rẹ̀.

20. Angẹli Ọlọrun náà wí fún un pé, “Da ẹran náà ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ náà lé gbogbo rẹ̀ lórí.” Gideoni sì ṣe bẹ́ẹ̀.

21. Angẹli OLUWA náà bá na ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi ṣóńṣó orí rẹ̀ kan ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà; iná bá ṣẹ́ lára àpáta, ó sì jó ẹran ati burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu náà. Angẹli OLUWA náà bá rá mọ́ ọn lójú.

22. Nígbà náà ni Gideoni tó mọ̀ pé angẹli OLUWA ni, ó bá dáhùn pé, “Yéè! OLUWA Ọlọrun, mo gbé! Nítorí pé mo ti rí angẹli OLUWA lojukooju.”

23. Ṣugbọn OLUWA dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, má bẹ̀rù, o kò ní kú.”

24. Gideoni bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA, ó pe orúkọ rẹ̀ ní “OLUWA ni Alaafia.” Pẹpẹ náà wà ní Ofira ti ìdílé Abieseri títí di òní olónìí.

25. Ní òru ọjọ́ náà, OLUWA sọ fún Gideoni pé, “Mú akọ mààlúù baba rẹ ati akọ mààlúù mìíràn tí ó jẹ́ ọlọ́dún meje, wó pẹpẹ oriṣa Baali baba rẹ lulẹ̀, kí o sì gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

26. Kí o wá tẹ́ pẹpẹ kan fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ lórí òkítì ibi gegele náà. To àwọn òkúta rẹ̀ lérí ara wọn dáradára, lẹ́yìn náà mú akọ mààlúù keji kí o sì fi rú ẹbọ sísun. Igi ère oriṣa Aṣera tí o bá gé lulẹ̀ ni kí o fi ṣe igi ẹbọ sísun náà.”

27. Gideoni mú mẹ́wàá ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì ṣe bí OLUWA ti ní kí ó ṣe, ṣugbọn kò lè ṣe é lọ́sàn-án, nítorí ẹ̀rù àwọn ará ilé ati àwọn ará ìlú rẹ̀ ń bà á, nítorí náà lóru ni ó ṣe é.

28. Nígbà tí àwọn ará ìlú náà jí ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n rí i pé, wọ́n ti wó pẹpẹ oriṣa Baali lulẹ̀, wọ́n sì ti gé ère oriṣa Aṣera tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ati pé wọ́n ti fi mààlúù keji rúbọ lórí pẹpẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́.

29. Wọ́n bá ń bi ara wọn léèrè pé, “Ta ló dán irú èyí wò?” Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti wádìí, wọ́n ní, “Gideoni ọmọ Joaṣi ni ó ṣe é.”

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 6