Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 3:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA fi àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi sílẹ̀ láti fi dán Israẹli wò, pàápàá jùlọ, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọn kò tíì ní ìrírí ogun jíjà ní ilẹ̀ Kenaani.

2. Kí àwọn ọmọ Israẹli lè mọ̀ nípa ogun jíjà, pataki jùlọ, ìṣọ̀wọ́ àwọn tí wọn kò mọ̀ nípa ogun jíjà tẹ́lẹ̀.

3. Àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA fi sílẹ̀ nìwọ̀nyí: àwọn olú-ìlú Filistini maraarun ati gbogbo ilẹ̀ Kenaani, àwọn ará Sidoni ati àwọn ará Hifi tí wọn ń gbé òkè Lẹbanoni, láti òkè Baali Herimoni títí dé ẹnubodè Hamati.

4. Àwọn ni OLUWA fi dán àwọn ọmọ Israẹli wò, láti wò ó bóyá wọn óo mú àṣẹ tí òun pa fún àwọn baba wọn láti ọwọ́ Mose ṣẹ, tabi wọn kò ní mú un ṣẹ.

5. Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ààrin àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti, àwọn ará Amori ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi.

6. Àwọn ọmọ Israẹli ń fẹ́mọ lọ́wọ́ àwọn eniyan orílẹ̀-èdè náà, àwọn náà ń fi ọmọ fún wọn; àwọn ọmọ Israẹli sì ń bọ àwọn oriṣa wọn.

7. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa Baali ati Aṣerotu.

8. Nítorí náà, inú bí OLUWA sí wọn, ó sì fi wọ́n lé Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lọ́wọ́; wọn sì sìn ín fún ọdún mẹjọ.

9. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n kígbe pé OLUWA, OLUWA gbé olùdáǹdè kan dìde fún wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Otinieli, ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu, òun ni ó gbà wọ́n kalẹ̀.

10. Ẹ̀mí OLUWA bà lé e, ó sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Ó jáde lọ sí ojú ogun, OLUWA sì fi Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lé e lọ́wọ́, ó sì ṣẹgun rẹ̀.

11. Nítorí náà, ilẹ̀ náà wà ní alaafia fún ogoji ọdún, lẹ́yìn náà, Otinieli ọmọ Kenasi ṣaláìsí.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 3