17. Wọ́n bá dáhùn pé, “Àwọn tí wọ́n kù ninu àwọn ara Bẹnjamini gbọdọ̀ ní ogún tiwọn, kí odidi ẹ̀yà kan má baà parun patapata ní Israẹli.
18. Ṣugbọn sibẹsibẹ, a kò gbọdọ̀ fi àwọn ọmọ wa fún wọn.” Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti búra pé, “Ẹni ègún ni ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọmọ fún ará Bẹnjamini.”
19. Wọ́n bá pinnu pé, “Ọdọọdún ni a máa ń ṣe àjọ̀dún OLUWA ní Ṣilo, tí ó wà ní apá àríwá Bẹtẹli, ní apá ìlà oòrùn òpópó ọ̀nà tí ó lọ láti Bẹtẹli sí Ṣekemu, ní apá gúsù Lebona.”
20. Wọ́n bá fún àwọn ọkunrin Bẹnjamini láṣẹ pé, “Ẹ lọ ba ní ibùba ninu ọgbà àjàrà,
21. kí ẹ máa ṣọ́ àwọn ọmọbinrin Ṣilo bí wọ́n bá wá jó; ẹ jáde láti inú ọgbà àjàrà, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ki iyawo kọ̀ọ̀kan mọ́lẹ̀ ninu àwọn ọmọbinrin Ṣilo, kí ẹ sì gbé wọn sá lọ sí ilẹ̀ Bẹnjamini.
22. Nígbà tí àwọn baba wọn, tabi àwọn arakunrin wọn bá wá fi ẹjọ́ sùn wá, a óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún wọn nítorí pé àwọn obinrin tí a rí fún wọn ninu ogún kò kárí; kì í kúkú ṣe pé ẹ fi àwọn ọmọbinrin wọnyi fún wọn ni, tí ègún yóo fi ṣẹ le yín lórí.’ ”