Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 18:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò kan, kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli, ati pé, ní àkókò náà, àwọn ẹ̀yà Dani ń wá ilẹ̀ tí wọn yóo gbà, tí wọn yóo sì máa gbé, nítorí pé, títí di àkókò yìí wọn kò tíì fún wọn ní ilẹ̀ kankan láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli.

2. Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Dani rán akikanju marun-un láàrin àwọn eniyan wọn, láti ìlú Sora ati Eṣitaolu, kí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà kí wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n wí fún àwọn amí náà pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì yẹ ilẹ̀ náà wò.” Wọ́n bá gbéra, wọ́n lọ sí agbègbè olókè ti Efuraimu. Nígbà tí wọ́n dé ilé Mika, wọ́n wọ̀ sibẹ.

3. Nígbà tí wọ́n wà ní ilé Mika, wọ́n ṣàkíyèsí bí ọdọmọkunrin tí ó wà ní ilé Mika ṣe ń sọ̀rọ̀, wọ́n sì mọ̀ pé ọmọ Lefi ni. Wọ́n bá bi í pé, “Ta ló mú ọ wá síhìn-ín? Kí ni ò ń ṣe níhìn-ín? Kí sì ni iṣẹ́ rẹ?”

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 18