Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 14:17-20 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ni iyawo rẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀ sí sọkún títí gbogbo ọjọ́ mejeeje tí wọ́n fi se àsè náà. Ṣugbọn nígbà tí ó di ọjọ́ keje, Samsoni sọ fún un, nítorí pé ó fún un lọ́rùn gidigidi. Obinrin náà bá lọ sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ará ìlú rẹ̀.

18. Nígbà tí ó di ọjọ́ keje, kí ó tó di pé oòrùn wọ̀, àwọn ará ìlú rẹ̀ náà wá sọ ìtumọ̀ àlọ́ Samsoni wí pé,“Kí ló dùn ju oyin lọ;kí ló lágbára ju kinniun lọ?”Ó ní,“Bí kò bá jẹ́ pé mààlúù mi ni ẹ fi tulẹ̀,ẹ kì bá tí lè túmọ̀ àlọ́ mi.”

19. Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé e tagbára tagbára, ó lọ sí Aṣikeloni, ó sì pa ọgbọ̀n ninu àwọn ọkunrin ìlú náà, ó kó ìkógun wọn, ó sì fún àwọn tí wọ́n túmọ̀ àlọ́ rẹ̀ ní aṣọ àríyá wọn; ó bá pada lọ sí ilé baba rẹ̀ pẹlu ibinu.

20. Wọ́n bá fi iyawo rẹ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní àkókò igbeyawo.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 14