Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 13:23-25 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Ṣugbọn iyawo rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Bí ó bá ṣe pé OLUWA fẹ́ pa wá ni, kò ní gba ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ tí a rú sí i lọ́wọ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi nǹkan wọnyi hàn wá, tabi kí ó sọ wọ́n fún wa.”

24. Nígbà tí ó yá, obinrin náà bí ọmọkunrin kan, ó sì sọ ọ́ ní Samsoni. Ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, OLUWA sì bukun un.

25. Ẹ̀mí OLUWA sì bẹ̀rẹ̀ sí lò ó ní Mahanedani, tí ó wà láàrin Sora ati Eṣitaolu.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 13