Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 12:9-15 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ó bí ọmọkunrin mejilelọgbọn, ó sì ní ọgbọ̀n ọmọbinrin. Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin fọ́kọ láàrin àwọn tí wọn kì í ṣe ìbátan rẹ̀, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n ọmọbinrin láti inú ẹ̀yà mìíràn wá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin. Ó jẹ́ aṣiwaju ní Israẹli fún ọdún meje.

10. Nígbà tí Ibisani ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Bẹtilẹhẹmu.

11. Lẹ́yìn Ibisani, Eloni, láti inú ẹ̀yà Sebuluni, jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹ́wàá.

12. Nígbà tí Eloni ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí Aijaloni ní ilẹ̀ Sebuluni.

13. Lẹ́yìn rẹ̀, Abidoni, ọmọ Hileli, ará Piratoni, jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli.

14. Ó ní ogoji ọmọkunrin ati ọgbọ̀n ọmọ ọmọ lọkunrin, tí wọn ń gun aadọrin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹjọ.

15. Lẹ́yìn náà, Abidoni ọmọ Hileli ará Piratoni ṣaláìsí, wọ́n sì sin ín sí Piratoni, ní ilẹ̀ Efuraimu, ní agbègbè olókè àwọn ará Amaleki.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 12