Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 1:6-19 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Adonibeseki sá, ṣugbọn wọ́n lé e mú. Wọ́n gé àtàǹpàkò ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji.

7. Adonibeseki bá dáhùn pé, “Aadọrin ọba tí mo ti gé àtàǹpàkò ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ wọn, ni wọ́n máa ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tabili mi. Ẹ̀san ohun tí mo ṣe sí wọn ni Ọlọrun ń san fún mi yìí.” Wọ́n bá mú un wá sí Jerusalẹmu, ibẹ̀ ni ó sì kú sí.

8. Àwọn ọmọ Juda gbógun ti ìlú Jerusalẹmu; wọ́n gbà á, wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbébẹ̀, wọ́n sì sun ún níná.

9. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbógun ti àwọn ará ilẹ̀ Kenaani tí wọ́n ń gbé orí òkè, ati ìhà gúsù tí à ń pè ní Nẹgẹbu, ati àwọn tí wọn ń gbé ẹsẹ̀ òkè náà pẹlu.

10. Àwọn ọmọ Juda tún lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé ìlú Heburoni, (Kiriati Araba ni orúkọ tí wọn ń pe Heburoni tẹ́lẹ̀); wọ́n ṣẹgun Ṣeṣai, Ahimani ati Talimai.

11. Nígbà tí wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ gbógun ti ìlú Debiri. (Kiriati Seferi ni orúkọ tí wọ́n ń pe Debiri tẹ́lẹ̀.)

12. Kalebu ní ẹnikẹ́ni tí ó bá gbógun ti ìlú Kiriati Seferi tí ó sì ṣẹgun rẹ̀, ni òun óo fi Akisa, ọmọbinrin òun fún kí ó fi ṣe aya.

13. Otinieli, ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu, ṣẹgun ìlú náà, Kalebu bá fi Akisa, ọmọbinrin rẹ̀ fún un kí ó fi ṣe aya.

14. Nígbà tí Akisa dé ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tọrọ pápá ìdaran lọ́wọ́ baba rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, Akisa lọ bá baba rẹ̀, bí ó ti ń sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni baba rẹ̀ bi í pé, “Kí lo fẹ́?”

15. Ó bá dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Ẹ̀bùn kan ni mo fẹ́ tọrọ. Ṣé o mọ̀ pé ilẹ̀ aṣálẹ̀ ni o fún mi; nítorí náà, fún mi ní orísun omi pẹlu rẹ̀.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí ó wà ní òkè ati ní ìsàlẹ̀.

16. Àwọn ọmọ ọmọ Keni, àna Mose, bá àwọn ọmọ Juda lọ láti Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ, sí inú aṣálẹ̀ Juda tí ó wà ní apá ìhà gúsù lẹ́bàá Aradi; wọ́n sì jọ ń gbé pọ̀ níbẹ̀.

17. Àwọn ọmọ Juda bá àwọn ọmọ Simeoni, arakunrin wọn, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí wọ́n ń gbé Sefati. Wọ́n gbógun tì wọ́n, wọ́n run wọ́n patapata, wọ́n sì sọ ìlú náà ní Horima.

18. Àwọn ọmọ Juda ṣẹgun ìlú Gasa ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè rẹ̀. Wọ́n ṣẹgun ìlú Aṣikeloni ati Ekironi ati àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè wọn.

19. OLUWA wà pẹlu àwọn ọmọ Juda, ọwọ́ wọn tẹ àwọn ìlú olókè, ṣugbọn apá wọn kò ká àwọn tí ó ń gbé pẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé irin ni wọ́n fi ṣe kẹ̀kẹ́ ogun wọn.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 1