Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 1:30-34 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Àwọn ọmọ Sebuluni kò lé àwọn tí wọ́n ń gbé ìlú Kitironi jáde, ati àwọn tí ó ń gbé Nahalali, ṣugbọn àwọn ará Kenaani ń bá wọn gbé, àwọn ọmọ Sebuluni sì ń fi tipátipá kó wọn ṣiṣẹ́.

31. Àwọn ọmọ Aṣeri náà kò lé àwọn wọnyi jáde: àwọn ará Ako ati àwọn ará Sidoni, àwọn ará Ahilabu ati àwọn ará Akisibu, àwọn ará Heliba ati àwọn ará Afeki, ati àwọn ará Rehobu.

32. Ṣugbọn àwọn ọmọ Aṣeri ń gbé ààrin àwọn ará Kenaani tí wọ́n bá ní ilẹ̀ náà, nítorí pé wọn kò lé wọn jáde.

33. Àwọn ará Nafutali kò lé àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ati àwọn ará Betanati jáde, ṣugbọn wọ́n ń gbé ààrin àwọn tí wọ́n bá ni ilẹ̀ Kenaani. Ṣugbọn wọ́n ń fi tipátipá kó àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ati ti Betanati ṣiṣẹ́.

34. Àwọn ará Amori ń lé àwọn ọmọ Dani sẹ́yìn sí àwọn agbègbè olókè, nítorí pé wọn kò fẹ́ gba àwọn ọmọ Dani láàyè rárá láti sọ̀kalẹ̀ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 1