Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 1:3-16 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Àwọn ọmọ Juda bá tọ ẹ̀yà Simeoni, arakunrin wọn lọ, wọ́n ní, “Ẹ bá wa lọ síbi ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wa, kí á lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani. Nígbà tí ó bá yá, àwa náà yóo ba yín lọ síbi ilẹ̀ tí wọ́n pín fun yín.” Àwọn ẹ̀yà Simeoni bá tẹ̀lé wọn.

4. Àwọn ọmọ Juda gbéra, wọ́n lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi. OLUWA fi wọ́n lé àwọn ọmọ Juda lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹgun ẹgbaarun (10,000) ninu wọn ní Beseki.

5. Wọ́n bá Adonibeseki ní Beseki, wọ́n gbógun tì í, wọ́n sì ṣẹgun àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi.

6. Adonibeseki sá, ṣugbọn wọ́n lé e mú. Wọ́n gé àtàǹpàkò ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji.

7. Adonibeseki bá dáhùn pé, “Aadọrin ọba tí mo ti gé àtàǹpàkò ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ wọn, ni wọ́n máa ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tabili mi. Ẹ̀san ohun tí mo ṣe sí wọn ni Ọlọrun ń san fún mi yìí.” Wọ́n bá mú un wá sí Jerusalẹmu, ibẹ̀ ni ó sì kú sí.

8. Àwọn ọmọ Juda gbógun ti ìlú Jerusalẹmu; wọ́n gbà á, wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbébẹ̀, wọ́n sì sun ún níná.

9. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbógun ti àwọn ará ilẹ̀ Kenaani tí wọ́n ń gbé orí òkè, ati ìhà gúsù tí à ń pè ní Nẹgẹbu, ati àwọn tí wọn ń gbé ẹsẹ̀ òkè náà pẹlu.

10. Àwọn ọmọ Juda tún lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé ìlú Heburoni, (Kiriati Araba ni orúkọ tí wọn ń pe Heburoni tẹ́lẹ̀); wọ́n ṣẹgun Ṣeṣai, Ahimani ati Talimai.

11. Nígbà tí wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ gbógun ti ìlú Debiri. (Kiriati Seferi ni orúkọ tí wọ́n ń pe Debiri tẹ́lẹ̀.)

12. Kalebu ní ẹnikẹ́ni tí ó bá gbógun ti ìlú Kiriati Seferi tí ó sì ṣẹgun rẹ̀, ni òun óo fi Akisa, ọmọbinrin òun fún kí ó fi ṣe aya.

13. Otinieli, ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu, ṣẹgun ìlú náà, Kalebu bá fi Akisa, ọmọbinrin rẹ̀ fún un kí ó fi ṣe aya.

14. Nígbà tí Akisa dé ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tọrọ pápá ìdaran lọ́wọ́ baba rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, Akisa lọ bá baba rẹ̀, bí ó ti ń sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni baba rẹ̀ bi í pé, “Kí lo fẹ́?”

15. Ó bá dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Ẹ̀bùn kan ni mo fẹ́ tọrọ. Ṣé o mọ̀ pé ilẹ̀ aṣálẹ̀ ni o fún mi; nítorí náà, fún mi ní orísun omi pẹlu rẹ̀.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí ó wà ní òkè ati ní ìsàlẹ̀.

16. Àwọn ọmọ ọmọ Keni, àna Mose, bá àwọn ọmọ Juda lọ láti Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ, sí inú aṣálẹ̀ Juda tí ó wà ní apá ìhà gúsù lẹ́bàá Aradi; wọ́n sì jọ ń gbé pọ̀ níbẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 1