Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 1:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn ikú Joṣua, àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ẹ̀yà wo ni kí ó kọ́kọ́ gbógun ti àwọn ará Kenaani?”

2. OLUWA dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yà Juda ni kí ó kọ́ dojú kọ wọ́n, nítorí pé, mo ti fi ilẹ̀ náà lé wọn lọ́wọ́.”

3. Àwọn ọmọ Juda bá tọ ẹ̀yà Simeoni, arakunrin wọn lọ, wọ́n ní, “Ẹ bá wa lọ síbi ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wa, kí á lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani. Nígbà tí ó bá yá, àwa náà yóo ba yín lọ síbi ilẹ̀ tí wọ́n pín fun yín.” Àwọn ẹ̀yà Simeoni bá tẹ̀lé wọn.

4. Àwọn ọmọ Juda gbéra, wọ́n lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi. OLUWA fi wọ́n lé àwọn ọmọ Juda lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹgun ẹgbaarun (10,000) ninu wọn ní Beseki.

5. Wọ́n bá Adonibeseki ní Beseki, wọ́n gbógun tì í, wọ́n sì ṣẹgun àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi.

6. Adonibeseki sá, ṣugbọn wọ́n lé e mú. Wọ́n gé àtàǹpàkò ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 1