Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Amosi 3:4-9 BIBELI MIMỌ (BM)

4. “Ṣé kinniun a máa bú ninu igbó láìjẹ́ pé ó ti pa ẹran?“Àbí ọmọ kinniun a máa bú ninu ihò rẹ̀ láìṣe pé ọwọ́ rẹ̀ ti ba nǹkan?

5. “Ṣé tàkúté a máa mú ẹyẹ nílẹ̀, láìṣe pé eniyan ló dẹ ẹ́ sibẹ?“Àbí tàkúté a máa ta lásán láìṣe pé ó mú nǹkan?

6. “Ṣé eniyan lè fọn fèrè ogun láàrin ìlú kí àyà ará ìlú má já?“Àbí nǹkan ibi lè ṣẹlẹ̀ ní ìlú láìṣe pé OLUWA ni ó ṣe é?

7. “Dájúdájú OLUWA Ọlọrun kì í ṣe ohunkohun láì kọ́kọ́ fi han àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀.

8. “Kinniun bú ramúramù, ta ni ẹ̀rù kò ní bà?“OLUWA Ọlọrun ti sọ̀rọ̀, ta ló gbọdọ̀ má sọ àsọtẹ́lẹ̀?”

9. Kéde fún àwọn ibi ààbò Asiria, ati àwọn ibi ààbò ilẹ̀ Ijipti, sọ pé: “Ẹ kó ara yín jọ sí orí àwọn òkè Samaria, kí ẹ sì wo rúdurùdu ati ìninilára tí ń ṣẹlẹ̀ ninu rẹ̀.

Ka pipe ipin Amosi 3