Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Amosi 3:11-15 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ọ̀tá yóo yí ilẹ̀ náà po, wọn yóo wó ibi ààbò yín, wọn yóo sì kó ìṣúra tí ó wà ní àwọn ilé ìṣúra rẹ̀.”

12. OLUWA ní: “Bí olùṣọ́-aguntan tií rí àjẹkù ẹsẹ̀ meji péré, tabi etí kan gbà kalẹ̀ lẹ́nu kinniun, ninu odidi àgbò, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn ọmọ Israẹli, tí ń gbé Samaria: díẹ̀ ninu wọn ni yóo là, àwọn tí wọn ń sùn lórí ibùsùn olówó iyebíye.”

13. OLUWA Ọlọrun, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ gbọ́, kí ẹ sì kìlọ̀ fún ìdílé Jakọbu.

14. Ní ọjọ́ tí n óo bá jẹ Israẹli níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, n óo jẹ pẹpẹ Bẹtẹli níyà, n óo kán àwọn ìwo tí ó wà lára pẹpẹ, wọn yóo sì bọ́ sílẹ̀.

15. N óo wó ilé tí ẹ kọ́ fún ìgbà òtútù ati èyí tí ẹ kọ́ fún ìgbà ooru; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ilé tí ẹ fi eyín erin kọ́ ati àwọn ilé ńláńlá yín yóo parẹ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Amosi 3