Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 9:5-18 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Gbogbo bàtà àwọn ológun, tí ń kilẹ̀ lójú ogun,ati gbogbo ẹ̀wù tí wọ́n ti yí mọ́lẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ni a óo dáná sun,iná yóo sì jó wọn run.

6. Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,a fún wa ní ọmọkunrin kan.Òun ni yóo jọba lórí wa.A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn,Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé,Ọmọ-Aládé alaafia.

7. Ìjọba rẹ̀ yóo máa tóbi sí i,alaafia kò sì ní lópin ní ìjọba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi.Yóo fìdí rẹ̀ múlẹ̀,yóo sì gbé e ró pẹlu ẹ̀tọ́ ati òdodo,láti ìgbà yìí lọ, títí ayérayé.Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí

8. OLUWA ranṣẹ ìdájọ́ sí Jakọbu,àní, sórí àwọn ọmọ Israẹli.

9. Gbogbo eniyan ni yóo mọ̀,àwọn ará Efuraimu ati àwọn ará Samaria,àwọn tí wọn ń fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé:

10. Ṣé bíríkì ni wọ́n fi kọ́ àwọn ilé tí ó wó lulẹ̀?Òkúta gbígbẹ́ ni a óo fi tún wọn kọ́.Igi sikamore ni a fi kọ́ èyí tí wọ́n dà wó,ṣugbọn igi kedari dáradára ni a óo lò dípò wọn.

11. Nítorí náà OLUWA ti gbé ọ̀tá dìde sí wọn:Ó ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè sí wọn:

12. Àwọn ará Siria láti ìhà ìlà oòrùn,ati àwọn ará Filistia láti ìhà ìwọ̀ oòrùn;wọn óo gbé Israẹli mì.Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.

13. Sibẹsibẹ àwọn ọmọ Israẹli kò pada sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó jẹ wọ́n níyà,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò wá OLUWA àwọn ọmọ-ogun.

14. Nítorí náà, OLUWA yóo fi ìyà jẹ Israẹli.Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, yóo gé Israẹli lórí ati nírù.

15. Àwọn àgbààgbà ati àwọn ọlọ́lá wọn ni orí,àwọn wolii tí ń kọ́ àwọn eniyan ní ẹ̀kọ́ èké sì ni ìrù

16. Àwọn tí ń darí àwọn eniyan wọnyi ń ṣì wọ́n lọ́nà ni,àwọn tí wọn ń tọ́ sọ́nà sì ń já sinu ìparun.

17. Nítorí náà, OLUWA kò láyọ̀ lórí àwọn ọdọmọkunrin wọn,àánú àwọn aláìníbaba ati àwọn opó wọn kò sì ṣe énítorí pé aṣebi ni gbogbo wọn, wọn kò sì mọ Ọlọrun,ọ̀rọ̀ burúkú ni wọ́n sì ń fi ẹnu wọn sọ.Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.

18. Ìwà burúkú wọn ń jó bí iná,tí ń jó ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn.Ó ń jó bíi igbó ńlá, ó sì ń yọ èéfín sókè lálá.

Ka pipe ipin Aisaya 9