Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 9:3-8 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ó ti bukun orílẹ̀-èdè náà.Ó ti fi kún ayọ̀ wọn;wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ̀, bí ayọ̀ ìgbà ìkórè.Bí inú àwọn eniyan ti máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń pín ìkógun.

4. Nítorí pé ó ti ṣẹ́ àjàgà tí ó wọ̀ wọ́n lọ́rùn,ati ọ̀pá tí wọn fí ń ru ẹrù sí èjìká,ati kùmọ̀ àwọn tí ń fìyà jẹ wọ́n.Ó ti ṣẹ́ wọn, bí ìgbà tí ó ṣẹ́ ti àwọn ará Midiani.

5. Gbogbo bàtà àwọn ológun, tí ń kilẹ̀ lójú ogun,ati gbogbo ẹ̀wù tí wọ́n ti yí mọ́lẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ni a óo dáná sun,iná yóo sì jó wọn run.

6. Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,a fún wa ní ọmọkunrin kan.Òun ni yóo jọba lórí wa.A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn,Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé,Ọmọ-Aládé alaafia.

7. Ìjọba rẹ̀ yóo máa tóbi sí i,alaafia kò sì ní lópin ní ìjọba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi.Yóo fìdí rẹ̀ múlẹ̀,yóo sì gbé e ró pẹlu ẹ̀tọ́ ati òdodo,láti ìgbà yìí lọ, títí ayérayé.Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí

8. OLUWA ranṣẹ ìdájọ́ sí Jakọbu,àní, sórí àwọn ọmọ Israẹli.

Ka pipe ipin Aisaya 9