Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 8:14-22 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Yóo di ibi-mímọ́ ati òkúta ìdìgbòlù, ati àpáta tí ó ń mú kí eniyan kọsẹ̀, fún ilẹ̀ Israẹli mejeeji. Yóo di ẹ̀bìtì ati tàkúté fún àwọn ará Jerusalẹmu.

15. Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo kọsẹ̀ níbẹ̀; wọn yóo ṣubú, wọn yóo sì fọ́ wẹ́wẹ́. Tàkúté yóo mú wọn, ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n.”

16. Di ẹ̀rí náà, fi èdìdì di ẹ̀kọ́ náà láàrin àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi.

17. N óo dúró de OLUWA ẹni tí ó fojú pamọ́ fún ilé Jakọbu, n óo sì ní ìrètí ninu rẹ̀.

18. Ẹ wò ó! Èmi ati àwọn ọmọ tí OLUWA fún mi, a wà fún àmì ati ìyanu ní Israẹli láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí ń gbé orí òkè Sioni.

19. Nígbà tí wọ́n bá wí fun yín pé kí ẹ lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn àjẹ́ ati àwọn abókùúsọ̀rọ̀ tí wọn ń jẹ ẹnu wúyẹ́-wúyẹ́. Ṣé kò yẹ kí orílẹ̀-èdè wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun wọn? Ṣé lọ́dọ̀ òkú ni ó ti yẹ kí alààyè ti máa wádìí ọ̀rọ̀?

20. Ẹ lọ wádìí ninu ẹ̀kọ́ mímọ́ ati ẹ̀rí. Bí ẹnìkan bá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí, kò sí òye ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀.

21. Wọn yóo kọjá lọ lórí ilẹ̀ náà ninu ìnira ati ebi; nígbà tí ebi bá pa wọ́n, wọn yóo máa kanra, wọn óo gbé ojú wọn sókè, wọn óo sì gbé ọba ati Ọlọrun wọn ṣépè.

22. Wọn óo bojú wo ilẹ̀, kìkì ìdààmú ati òkùnkùn ati ìṣúdudu ati ìnira ni wọn óo rí. A óo sì sọ wọ́n sinu òkùnkùn biribiri.

Ka pipe ipin Aisaya 8