Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 8:10-17 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Bí ẹ gbìmọ̀ pọ̀ ìmọ̀ yín yóo di òfo.Ohun yòówù tí ẹ lè sọ, àpérò yín yóo di asán.Nítorí pé Ọlọrun wà pẹlu wa.

11. Nítorí ọwọ́ agbára ni OLUWA fi lé mi lára, nígbà tí ó ń sọ èyí fún mi. Ó sì ti kìlọ̀ fún mi pé kí n má bá àwọn eniyan wọnyi rìn, ó ní,

12. “Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ tí àwọn eniyan yìí ń dì. Bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bẹ̀rù ohun tí wọn ń bẹ̀rù.

13. OLUWA àwọn ọmọ ogun nìkan ni kí o kà sí mímọ́, òun ni kí ẹ̀rù rẹ̀ máa bà ọ́. Òun nìkan ni kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa pá ọ láyà.

14. Yóo di ibi-mímọ́ ati òkúta ìdìgbòlù, ati àpáta tí ó ń mú kí eniyan kọsẹ̀, fún ilẹ̀ Israẹli mejeeji. Yóo di ẹ̀bìtì ati tàkúté fún àwọn ará Jerusalẹmu.

15. Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo kọsẹ̀ níbẹ̀; wọn yóo ṣubú, wọn yóo sì fọ́ wẹ́wẹ́. Tàkúté yóo mú wọn, ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n.”

16. Di ẹ̀rí náà, fi èdìdì di ẹ̀kọ́ náà láàrin àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi.

17. N óo dúró de OLUWA ẹni tí ó fojú pamọ́ fún ilé Jakọbu, n óo sì ní ìrètí ninu rẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 8