Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 7:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà ayé Ahasi, ọmọ Jotamu, ọmọ Usaya, ọba Juda, Resini Ọba Siria ati Peka ọmọ Remalaya, ọba Israẹli wá gbé ogun ti Jerusalẹmu, ṣugbọn wọn kò lè ṣẹgun rẹ̀.

2. Nígbà tí ìròyìn dé ilé ọba Dafidi pé àwọn ará Siria ati Efuraimu ń gbógun bọ̀, ọkàn òun ati àwọn eniyan rẹ̀ mì tìtì bí afẹ́fẹ́ tíí mi igi ninu igbó.

3. OLUWA sọ fún Aisaya pé, “Lọ bá Ahasi, ìwọ ati Ṣeari Jaṣubu, ọmọ rẹ, ní òpin ibi tí wọ́n fa omi dé ní ọ̀nà àwọn alágbàfọ̀.

4. Kí o sọ fún un pé, ṣọ́ra, farabalẹ̀, má sì bẹ̀rù. Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ já rárá nítorí ibinu gbígbóná Resini ati Siria, ati ti ọmọ Remalaya, nítorí wọn kò yàtọ̀ sí àjókù igi iná meji tí ń rú èéfín.

5. Nítorí pé Siria, pẹlu Efuraimu ati ọmọ Remalaya ti pète ati ṣe ọ́ ní ibi. Wọ́n ń sọ pé,

6. ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ gbógun ti Juda, kí á dẹ́rùbà á, ẹ jẹ́ kí á ṣẹgun rẹ̀ kí á sì gbà á, kí á fi ọmọ Tabeeli jọba lórí rẹ̀!’

7. “Àbá tí wọn ń dá kò ní ṣẹ, ète tí wọn ń pa kò ní rí bẹ́ẹ̀.

8. Ṣebí Damasku ni olú-ìlú Siria, Resini sì ni olórí Damasku. Láàrin ìsinyìí sí ọdún marundinlaadọrin, Efuraimu yóo fọ́nká, kò sì ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́.

Ka pipe ipin Aisaya 7