Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 66:22-24 BIBELI MIMỌ (BM)

22. “Bí ọ̀run tuntun ati ayé tuntun tí n óo dá, yóo ṣe máa wà níwájú mi, bẹ́ẹ̀ ni arọmọdọmọ ati orúkọ rẹ̀ yóo máa wà.

23. Láti oṣù tuntun dé oṣù tuntun, ati láti ọjọ́ ìsinmi kan dé ekeji, ni gbogbo eniyan yóo máa wá jọ́sìn níwájú mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

24. Wọn óo jáde, wọn óo sì fojú rí òkú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí mi; nítorí ìdin tí ń jẹ wọ́n kò ní kú, bẹ́ẹ̀ ni iná tí ń jó wọn kò ní kú; wọn óo sì jẹ́ ohun ìríra lójú gbogbo eniyan.”

Ka pipe ipin Aisaya 66