Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 66:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní:“Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.Ilé tí ẹ kọ́ fún mi dà?Níbo sì ni ibi ìsinmi mi wà?

2. Ọwọ́ mi ni mo fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi,tèmi sì ni gbogbo wọn.Ẹni tí n óo kà kún,ni onírẹ̀lẹ̀ ati oníròbìnújẹ́ eniyan, tí ó ń wárìrì nítorí ọ̀rọ̀ mi.

3. “Ati ẹni tí ó pa mààlúù rúbọ,ati ẹni tí ó pa eniyan;kò sí ìyàtọ̀.Ẹni tí ó fi ọ̀dọ́ aguntan rúbọ,kò yàtọ̀ sí ẹni tí ó lọ́ ajá lọ́rùn pa.Ati ẹni tí ó fi ọkà rúbọ,ati ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ,bákan náà ni wọ́n rí.Ẹni tí ó fi turari ṣe ẹbọ ìrántí,kò sì yàtọ̀ sí ẹni tí ó súre níwájú oriṣa.Wọ́n ti yan ọ̀nà tí ó wù wọ́n,wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn sin ohun ìríra wọn.

4. Èmi náà óo sì yan ìjìyà fún wọn,n óo jẹ́ kí ẹ̀rù wọn pada sórí wọn.Nítorí pé nígbà tí mo pè wọ́n, ẹnikẹ́ni wọn kò dáhùn;nígbà tí mo sọ̀rọ̀ fún wọn, wọn kò gbọ́,wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú mi,wọ́n yan ohun tí inú mi kò dùn sí.”

5. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wárìrì nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀:“Àwọn arakunrin yín tí wọn kórìíra yín,wọ́n tì yín síta nítorí orúkọ mi;wọ́n ní, ‘Jẹ́ kí OLUWA fi ògo rẹ̀ hàn,kí á lè rí ayọ̀ yín.’Ṣugbọn àwọn ni ojú yóo tì.

6. Ẹ gbọ́ ariwo ninu ìlú,ẹ gbọ́ ohùn kan láti inú Tẹmpili,ohùn OLUWA ni,ó ń san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

7. “Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, ó ti bímọ.Kí ìrora obí tó mú un,ó ti bí ọmọkunrin kan.

8. Ta ló gbọ́ irú èyí rí?Ta ló rí irú rẹ̀ rí?Ǹjẹ́ a lè bí ilẹ̀ ní ọjọ́ kan,tabi kí á bí orílẹ̀-èdè kan ní ọjọ́ kan?Ní kété tí Sioni bẹ̀rẹ̀ sí rọbí,ni ó bí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin.

9. Ṣé mo lè jẹ́ kí eniyan máa rọbí,kí n má jẹ́ kí ó bímọ bí?Èmi OLUWA, tí mò ń mú kí eniyan máa bímọ,ṣé, mo jẹ́ sé eniyan ninu?”

10. Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀, kí inú yín dùn nítorí rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀,ẹ bá a yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ nítorí rẹ̀.

11. Kí ẹ lè mu àmutẹ́rùn, ninu wàrà rẹ̀ tí ń tuni ninu;kí ẹ lè ní ànítẹ́rùn pẹlu ìdùnnú,ninu ọpọlọpọ ògo rẹ̀.

12. Nítorí OLUWA ní:“N óo tú ibukun sórí rẹ̀,bí ìgbà tí odò bá ń ṣàn.N óo da ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́,bí odò tí ò ṣàn kọjá bèbè.Yóo dà yín sẹ́gbẹ̀ẹ́ bí ọmọ tí ń mu ọmú,ẹ óo máa ṣeré lórí orúnkún rẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 66