Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 64:7-12 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Kò sí ẹnìkan tí ń gbadura ní orúkọ rẹ,kò sí ẹni tí ń ta ṣàṣà láti dìmọ́ ọ;nítorí pé o ti fojú pamọ́ fún wa,o sì ti pa wá tì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa.

8. Sibẹsibẹ OLUWA, ìwọ ni baba wa,amọ̀ ni wá, ìwọ sì ni amọ̀kòkò;iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni gbogbo wa.

9. OLUWA má bínú pupọ jù,má máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wa títí lae.Jọ̀wọ́, ro ọ̀rọ̀ wa wò,nítorí pé eniyan rẹ ni gbogbo wa.

10. Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀,Sioni ti di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu sì ti di ahoro.

11. Wọ́n ti dáná sun ilé mímọ́ wa tí ó lẹ́wà,níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́,gbogbo ibi dáradára tí a ní, ló ti di ahoro.

12. OLUWA, ṣé o kò ní ṣe nǹkankan sí ọ̀rọ̀ yìí ni?Ṣé o óo dákẹ́, o óo máa fìyà jẹ wá ni?

Ka pipe ipin Aisaya 64