Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 64:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ò bá jẹ́ fa awọsanma ya kí o sì sọ̀kalẹ̀,kí àwọn òkè ńlá máa mì tìtì níwájú rẹ;

2. bí ìgbà tí iná ń jó igbó ṣúúrú,tí iná sì ń mú kí omi hó.Kí orúkọ rẹ di mímọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ,kí àwọn orílẹ̀-èdè lè máa gbọ̀n níwájú rẹ!

3. Nígbà tí o bá ṣe nǹkan tí ó bani lẹ́rù,tí ẹnikẹ́ni kò retí,o sọ̀kalẹ̀, àwọn òkè ńlá sì mì tìtì níwájú rẹ.

4. Láti ìgbà àtijọ́, ẹnìkan kò gbọ́ rí,bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò tíì fi ojú rí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ,tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.

5. Ò máa ran àwọn tí ń fi inú dídùn ṣiṣẹ́ òdodo lọ́wọ́,àwọn tí wọn ranti rẹ ninu ìgbé ayé wọn,o bínú, nítorí náà a dẹ́ṣẹ̀,a ti wà ninu ẹ̀ṣẹ̀ wa tipẹ́.Ǹjẹ́ a óo rí ìgbàlà?

6. Gbogbo wa dàbí aláìmọ́,gbogbo iṣẹ́ òdodo wa dàbí àkísà ẹlẹ́gbin.Gbogbo wa rọ bí ewé,àìdára wa sì ń fẹ́ wa lọ bí atẹ́gùn.

Ka pipe ipin Aisaya 64