Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 63:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Ta ni ń ti Edomu bọ̀ yìí,tí ó wọ aṣọ àlàárì, tí ń bọ̀ láti Bosira,tí ó yọ bí ọjọ́ ninu aṣọ tí ó wọ̀,tí ń yan bọ̀ ninu agbára ńlá rẹ̀.”“Èmi ni, èmi tí mò ń kéde ẹ̀san,tí mo sì lágbára láti gbani là.”

2. “Kí ló dé tí aṣọ rẹ fi pupa,tí ó dàbí ti ẹni tí ń fún ọtí waini?”

3. OLUWA dáhùn, ó ní, “Èmi nìkan ni mo tí ń fún ọtí waini,ẹnikẹ́ni kò bá mi fún un ninu àwọn eniyan mi.Mo fi ibinu tẹ̀ wọ́n bí èso àjàrà,mo fi ìrúnú tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.Ẹ̀jẹ̀ wọn bá dà sí mi láṣọ:ó ti di àbààwọ́n sára gbogbo aṣọ mi.

4. Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ló wà lọ́kàn mi,ọdún ìràpadà mi sì ti dé.

5. Mo wò yíká, ṣugbọn kò sí olùrànlọ́wọ́,ẹnu yà mí pé, n kò rí ẹnìkan tí yóo gbé mi ró;nítorí náà, agbára mi ni mo fi ṣẹgun,ibinu mi ni ó sì gbé mi ró.

6. Mo fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,mo fi ìrúnú rọ wọ́n yó,mo sì tú ẹ̀jẹ̀ wọn dà sílẹ̀.”

Ka pipe ipin Aisaya 63