Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 61:4-11 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Wọn óo tún àlàpà ahoro àtijọ́ kọ́,wọn óo tún gbogbo ilé tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́,wọn óo sì tún ìlú tí a ti parun láti ọdún gbọọrọ kọ́.

5. Àwọn àjèjì ni yóo máa ba yín bọ́ agbo ẹran yín,àwọn ni yóo sì máa ṣe alágbàṣe ninu ọgbà àjàrà yín;

6. ṣugbọn a óo máa pe ẹ̀yin ní alufaa OLUWA,àwọn eniyan yóo sì máa sọ̀rọ̀ yín bí iranṣẹ Ọlọrun wa.Ẹ̀yin ni ẹ óo máa jẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,ọrọ̀ wọn ni ẹ óo sì máa fi ṣògo.

7. Dípò ìtìjú ìpín tiyín yóo jẹ́ meji,dípò àbùkù ẹ óo láyọ̀ ninu ìpín tí ó kàn yín.Ìlọ́po meji ni ìpín yín yóo jẹ́ ninu ilẹ̀ yín,ayọ̀ ayérayé yóo sì jẹ́ tiyín.

8. OLUWA ní,“Nítorí pé mo fẹ́ ẹ̀tọ́,mo sì kórìíra ìfipá jalè ati ohun tí kò tọ́.Dájúdájú n óo san ẹ̀san fún wọn,n óo sì bá wọn dá majẹmu ayérayé.

9. Àwọn ọmọ wọn yóo dá yàtọ̀ láàrin orílẹ̀-èdè,a óo dá arọmọdọmọ wọn mọ̀ láàrin àwọn eniyan,gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn,yóo gbà pé èmi OLUWA ti bukun wọn.”

10. N óo máa yọ̀ ninu OLUWA,ọkàn mi yóo kún fún ayọ̀ sí Ọlọrun mi.Nítorí ó ti fi ìgbàlà wọ̀ mí bí ẹ̀wù,ó sì ti fi òdodo bòmí lára bí aṣọ;bí ọkọ iyawo tí ó ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́,ati bí iyawo tí ó ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì.

11. Bí ilẹ̀ tíí mú kí ewéko hù jáde,tí ọgbà sì ń mú kí ohun tí a gbìn sinu rẹ̀ hù,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun yóo mú kí òdodo ati orin ìyìn yọ jádeníwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.

Ka pipe ipin Aisaya 61