Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 61:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀mí OLUWA, Ọlọrun tí bà lé mi,nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mí,láti mú ìròyìn ayọ̀ wá fún àwọn tí a ni lára.Ó rán mi pé kí n máa tu àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ninu,kí n máa kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn,kí n sì máa ṣí ìlẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n.

2. Ó ní kí n máa kéde ọdún ojurere OLUWA,ati ọjọ́ ẹ̀san Ọlọrun wa;kí n sì máa tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ninu.

3. Ó ní kí n máa fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Sioni,ní inú dídùn dípò ìkáàánú,kí n fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́,kí n jẹ́ kí wọn máa kọrin ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn,kí á lè máa pè wọ́n ní igi òdodo,tí OLUWA gbìn,kí á lè máa yìn ín lógo.

4. Wọn óo tún àlàpà ahoro àtijọ́ kọ́,wọn óo tún gbogbo ilé tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́,wọn óo sì tún ìlú tí a ti parun láti ọdún gbọọrọ kọ́.

5. Àwọn àjèjì ni yóo máa ba yín bọ́ agbo ẹran yín,àwọn ni yóo sì máa ṣe alágbàṣe ninu ọgbà àjàrà yín;

6. ṣugbọn a óo máa pe ẹ̀yin ní alufaa OLUWA,àwọn eniyan yóo sì máa sọ̀rọ̀ yín bí iranṣẹ Ọlọrun wa.Ẹ̀yin ni ẹ óo máa jẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,ọrọ̀ wọn ni ẹ óo sì máa fi ṣògo.

Ka pipe ipin Aisaya 61