Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 6:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún tí Usaya Ọba kú, mo rí OLUWA: ó jókòó lórí ìtẹ́, a gbé e ga sókè, aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili.

2. Àwọn Serafu dúró lókè rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ìyẹ́ mẹfa mẹfa: ó fi meji bo ojú, ó fi meji bo ẹsẹ̀, ó sì ń fi meji fò.

3. Ekinni ń ké sí ekeji pé:“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun;gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”

4. Ìpìlẹ̀ ilé náà mì títí nígbà tí ẹni náà kígbe, èéfín sì kún ilé náà.

Ka pipe ipin Aisaya 6