Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 59:5-16 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ẹ̀ ń bá paramọ́lẹ̀ pa ẹyin rẹ̀,ẹ sì ń ran òwú aláǹtakùn,ẹni tí ó bá jẹ ninu ẹyin yín yóo kú.Bí ẹnìkan bá fọ́ ọ̀kan ninu ẹyin yín, ejò paramọ́lẹ̀ ni yóo jáde sí i.

6. Òwú aláǹtakùn yín kò lè di aṣọ,eniyan kò ní fi iṣẹ́ ọwọ́ yín bora.Iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni iṣẹ́ yín,ìwà ipá sì ń bẹ lọ́wọ́ yín.

7. Ẹsẹ̀ yín yá sí ọ̀nà ibi,ẹ sì yára sí àtipa aláìṣẹ̀.Èrò ẹ̀ṣẹ̀ ni èrò ọkàn yín.Ọ̀nà yín kún fún ìsọdahoro ati ìparun.

8. Ẹ kò mọ ọ̀nà alaafia,kò sí ìdájọ́ òdodo ní ọ̀nà yín.Ẹ ti mú kí ọ̀nà yín wọ́,ẹni tó bá ba yín rìn kò ní ní alaafia.

9. Àwọn eniyan bá dáhùn pé,“Nítorí náà ni ìdájọ́ òtítọ́ fi jìnnà sí wa,tí òdodo kò sì fi dé ọ̀dọ̀ wà.Ìmọ́lẹ̀ ni à ń retí, ṣugbọn òkùnkùn ló ṣú,ìtànṣán oòrùn ni à ń retí, ṣugbọn ìkùukùu ni ó bolẹ̀.

10. À ń táràrà lára ògiri bí afọ́jú,à ń táràrà bí ẹni tí kò lójú.À ń kọsẹ̀ lọ́sàn-án gangan,bí ẹni tí ó jáde ní àfẹ̀mọ́júmọ́a dàbí òkú láàrin àwọn alágbára.

11. Gbogbo wa ń bú bí ẹranko beari,a sì ń ké igbe ẹ̀dùn bí àdàbà.À ń retí ìdájọ́ òdodo, ṣugbọn kò sí;à ń retí ìgbàlà, ṣugbọn ó jìnnà sí wa.

12. “Nítorí àìdára wa pọ̀ níwájú rẹ,ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí lòdì sí wa;nítorí àwọn àìdára wa wà pẹlu wa,a sì mọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa:

13. A ń kọjá ààyè wa, à ń sẹ́ OLUWA,a sì ń yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun wa.Ọ̀rọ̀ ìninilára ati ọ̀tẹ̀ ni à ń sọ,èrò ẹ̀tàn ní ń bẹ lọ́kàn wa, ọ̀rọ̀ èké sì ní ń jáde lẹ́nu wa.

14. A fi ọwọ́ rọ́ ẹjọ́ ẹ̀tọ́ sẹ́yìn,òdodo sì takété.Òtítọ́ ti ṣubú ní gbangba ìdájọ́,ìdúróṣinṣin kò rọ́nà wọlé.

15. Òtítọ́ di ohun àwátì,ẹni tí ó yàgò fún iṣẹ́ ibi fi ara rẹ̀ fún ayé mú.”OLUWA rí i pé kò sí ìdájọ́ òdodo,ó sì bà á lọ́kàn jẹ́,

16. Ó rí i pé kò sí ẹnìkan tí yóo ṣe onílàjà,ẹnu sì yà á, pé kò sí ẹnìkankan.Ó bá fi ọwọ́ rẹ̀ ṣẹgun fún ara rẹ̀,òdodo rẹ̀ sì gbé e dúró.

Ka pipe ipin Aisaya 59