Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 59:3-8 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ìpànìyàn ti sọ ọwọ́ yín di aláìmọ́,ọwọ́ yín kún fún ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀ ń purọ́,ẹ sì ń fi ẹnu yín sọ ọ̀rọ̀ burúkú.

4. Kò sí ẹni tí ó ń pe ẹjọ́ àre,kò sì sí ẹni tí ó ń rojọ́ òdodo.Ẹjọ́ òfo ni ẹ gbójú lé.Ẹ kún fún irọ́ pípa, ìkà ń bẹ ninu yín,iṣẹ́ burúkú sì ń bẹ lọ́wọ́ yín.

5. Ẹ̀ ń bá paramọ́lẹ̀ pa ẹyin rẹ̀,ẹ sì ń ran òwú aláǹtakùn,ẹni tí ó bá jẹ ninu ẹyin yín yóo kú.Bí ẹnìkan bá fọ́ ọ̀kan ninu ẹyin yín, ejò paramọ́lẹ̀ ni yóo jáde sí i.

6. Òwú aláǹtakùn yín kò lè di aṣọ,eniyan kò ní fi iṣẹ́ ọwọ́ yín bora.Iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni iṣẹ́ yín,ìwà ipá sì ń bẹ lọ́wọ́ yín.

7. Ẹsẹ̀ yín yá sí ọ̀nà ibi,ẹ sì yára sí àtipa aláìṣẹ̀.Èrò ẹ̀ṣẹ̀ ni èrò ọkàn yín.Ọ̀nà yín kún fún ìsọdahoro ati ìparun.

8. Ẹ kò mọ ọ̀nà alaafia,kò sí ìdájọ́ òdodo ní ọ̀nà yín.Ẹ ti mú kí ọ̀nà yín wọ́,ẹni tó bá ba yín rìn kò ní ní alaafia.

Ka pipe ipin Aisaya 59