Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 59:2-5 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó fa ìyapa láàrin ẹ̀yin ati Ọlọrun yín,àìdára yín ni ó mú kí ó fojú pamọ́ fun yín,tí kò fi gbọ́ ẹ̀bẹ̀ yín.

3. Ìpànìyàn ti sọ ọwọ́ yín di aláìmọ́,ọwọ́ yín kún fún ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀ ń purọ́,ẹ sì ń fi ẹnu yín sọ ọ̀rọ̀ burúkú.

4. Kò sí ẹni tí ó ń pe ẹjọ́ àre,kò sì sí ẹni tí ó ń rojọ́ òdodo.Ẹjọ́ òfo ni ẹ gbójú lé.Ẹ kún fún irọ́ pípa, ìkà ń bẹ ninu yín,iṣẹ́ burúkú sì ń bẹ lọ́wọ́ yín.

5. Ẹ̀ ń bá paramọ́lẹ̀ pa ẹyin rẹ̀,ẹ sì ń ran òwú aláǹtakùn,ẹni tí ó bá jẹ ninu ẹyin yín yóo kú.Bí ẹnìkan bá fọ́ ọ̀kan ninu ẹyin yín, ejò paramọ́lẹ̀ ni yóo jáde sí i.

Ka pipe ipin Aisaya 59