Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 59:13-21 BIBELI MIMỌ (BM)

13. A ń kọjá ààyè wa, à ń sẹ́ OLUWA,a sì ń yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun wa.Ọ̀rọ̀ ìninilára ati ọ̀tẹ̀ ni à ń sọ,èrò ẹ̀tàn ní ń bẹ lọ́kàn wa, ọ̀rọ̀ èké sì ní ń jáde lẹ́nu wa.

14. A fi ọwọ́ rọ́ ẹjọ́ ẹ̀tọ́ sẹ́yìn,òdodo sì takété.Òtítọ́ ti ṣubú ní gbangba ìdájọ́,ìdúróṣinṣin kò rọ́nà wọlé.

15. Òtítọ́ di ohun àwátì,ẹni tí ó yàgò fún iṣẹ́ ibi fi ara rẹ̀ fún ayé mú.”OLUWA rí i pé kò sí ìdájọ́ òdodo,ó sì bà á lọ́kàn jẹ́,

16. Ó rí i pé kò sí ẹnìkan tí yóo ṣe onílàjà,ẹnu sì yà á, pé kò sí ẹnìkankan.Ó bá fi ọwọ́ rẹ̀ ṣẹgun fún ara rẹ̀,òdodo rẹ̀ sì gbé e dúró.

17. Ó gbé òdodo wọ̀ bí ìgbàyà,ó fi àṣíborí ìgbàlà borí.Ó gbé ẹ̀san wọ̀ bí ẹ̀wù,ó fi bora bí aṣọ.

18. Yóo san ẹ̀san fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn,yóo bínú sí àwọn tí wọ́n lòdì sí i,yóo sì san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀,ati àwọn tí ń gbé erékùṣù.

19. Wọn óo bẹ̀rù orúkọ OLUWA láti ìwọ̀ oòrùn,wọn óo bẹ̀rù ògo rẹ̀ láti ìlà oòrùn;nítorí yóo wá bí ìkún omi, tí ẹ̀fúùfù láti ọ̀dọ̀ OLUWA ń taari.

20. OLUWA ní, “N óo wá sí Sioni bí Olùràpadà,n óo wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Jakọbu,tí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀.

21. “Majẹmu tí Èmi bá wọn dá nìyí: Ẹ̀mí mi tí mo fi le yín lórí, ati ọ̀rọ̀ mi tí mo fi si yín lẹ́nu, kò gbọdọ̀ kúrò lẹ́nu yín, ati lẹ́nu àwọn ọmọ rẹ, ati lẹ́nu arọmọdọmọ yín, láti àkókò yìí lọ ati títí laelae. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Aisaya 59