Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 59:11-17 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Gbogbo wa ń bú bí ẹranko beari,a sì ń ké igbe ẹ̀dùn bí àdàbà.À ń retí ìdájọ́ òdodo, ṣugbọn kò sí;à ń retí ìgbàlà, ṣugbọn ó jìnnà sí wa.

12. “Nítorí àìdára wa pọ̀ níwájú rẹ,ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí lòdì sí wa;nítorí àwọn àìdára wa wà pẹlu wa,a sì mọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa:

13. A ń kọjá ààyè wa, à ń sẹ́ OLUWA,a sì ń yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun wa.Ọ̀rọ̀ ìninilára ati ọ̀tẹ̀ ni à ń sọ,èrò ẹ̀tàn ní ń bẹ lọ́kàn wa, ọ̀rọ̀ èké sì ní ń jáde lẹ́nu wa.

14. A fi ọwọ́ rọ́ ẹjọ́ ẹ̀tọ́ sẹ́yìn,òdodo sì takété.Òtítọ́ ti ṣubú ní gbangba ìdájọ́,ìdúróṣinṣin kò rọ́nà wọlé.

15. Òtítọ́ di ohun àwátì,ẹni tí ó yàgò fún iṣẹ́ ibi fi ara rẹ̀ fún ayé mú.”OLUWA rí i pé kò sí ìdájọ́ òdodo,ó sì bà á lọ́kàn jẹ́,

16. Ó rí i pé kò sí ẹnìkan tí yóo ṣe onílàjà,ẹnu sì yà á, pé kò sí ẹnìkankan.Ó bá fi ọwọ́ rẹ̀ ṣẹgun fún ara rẹ̀,òdodo rẹ̀ sì gbé e dúró.

17. Ó gbé òdodo wọ̀ bí ìgbàyà,ó fi àṣíborí ìgbàlà borí.Ó gbé ẹ̀san wọ̀ bí ẹ̀wù,ó fi bora bí aṣọ.

Ka pipe ipin Aisaya 59