Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 58:13-14 BIBELI MIMỌ (BM)

13. “Bí ẹ bá dẹ́kun láti máa ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́,tí ẹ kò sì máa ṣe ìfẹ́ inú yín lọ́jọ́ mímọ́ mi;bí ẹ bá pe ọjọ́ ìsinmi ní ọjọ́ ìdùnnú,tí ẹ pe ọjọ́ mímọ́ OLUWA ní ọjọ́ ológo;bí ẹ bá yẹ́ ẹ sí, tí ẹ kò yà sí ọ̀nà tiyín,tí ẹ kò máa ṣe ìfẹ́ inú ara yín,tabi kí ẹ máa sọ̀rọ̀ àhesọ;

14. nígbà náà ni inú yín yóo máa dùn láti sin èmi OLUWA,n óo gbe yín gun orí òkè ilẹ̀ ayé,n óo sì mu yín jogún Jakọbu, baba ńlá yín.Èmi OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Aisaya 58