Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 58:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Kígbe sókè, má dákẹ́,ké sókè bíi fèrè ogun,sọ ìrékọjá àwọn eniyan mi fún wọn ní àsọyé,sọ ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jakọbu fún wọn.

2. Nítòótọ́ ni wọ́n ń wá mi lojoojumọ,wọ́n sì fẹ́ mọ ìlànà mi,wọ́n ṣe bí orílẹ̀-èdè tí ó mọ òdodo,tí kò kọ òfin Ọlọrun wọn sílẹ̀.Wọ́n ń bèèrè ìdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ mi,wọ́n ní ìfẹ́ ati súnmọ́ Ọlọrun.”

3. Wọ́n ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí à ń gbààwẹ̀, ṣugbọn tí OLUWA kò rí wa?Tí à ń fìyà jẹ ara wa, ṣugbọn tí kò náání wa?”OLUWA wí pé,“Ìdí rẹ̀ ni pé,nígbà tí ẹ bá ń gbààwẹ̀, ẹ̀ máa ṣe ìfẹ́ ọkàn yín.Ẹ̀ sì máa ni gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ yín lára.

4. Ẹ̀ ń kún fún ìjà ati asọ̀ ní àkókò ààwẹ̀ yín,ẹ̀ ń lu ara yín ní ìlù ìkà.Irú ààwẹ̀ tí ẹ̀ ń gbà yìí kò ní jẹ́ kí Ọlọrun gbọ́ ohùn yín lọ́run.

5. Ṣé irú ààwẹ̀ tí mo yàn nìyí, ọjọ́ tí eniyan yóo rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ lásán?Ṣé kí eniyan lè doríkodò bíi koríko etí odò nìkan ni?Tabi kí ó lè jókòó lórí aṣọ ọ̀fọ̀ ati eérú nìkan?Ṣé èyí ni ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀, ati ọjọ́ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ OLUWA?

6. “Ṣebí irú ààwẹ̀ tí mo yàn ni pé:kí á tú ìdè ìwà burúkú,kí á yọ irin tí a fi di igi àjàgà;kí á dá àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́,kí á já gbogbo àjàgà?

7. Àní kí ẹ fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ,kí ẹ mú àwọn òtòṣì aláìnílé wá sinu ilé yín,bí ẹ bá rí ẹnikẹ́ni ní ìhòòhò, kí ẹ fi aṣọ bò ó,kí ẹ má sì fojú pamọ́ fún ẹni tí ó jẹ́ ẹbí yín.

Ka pipe ipin Aisaya 58