Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 56:2-8 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀,ati fún ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé e,tí ó ń ṣọ́ra, tí kò rú òfin ọjọ́ ìsinmi,tí kò sì fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe nǹkan burúkú.”

3. Kí àjèjì tí ó faramọ́ OLUWA má sọ pé,“Dájúdájú OLUWA yóo yà mí kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.”Kí ìwẹ̀fà má sì sọ pé,“Wò ó! Mo dàbí igi gbígbẹ.”

4. Nítorí OLUWA ní,“Bí ìwẹ̀fà kan bá pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,tí ó bá ṣe ohun tí mo fẹ́,tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,

5. n óo fún wọn ní ipò láàrin àgbàlá mi,ati ìrántí tí ó dára, ju ọmọkunrin ati ọmọbinrin lọ.Orúkọ tí kò ní parẹ́ laelae, ni n óo fún wọn.

6. “Àwọn àjèjì tí ó bá darapọ̀ mọ́ OLUWA, tí wọn ń sìn ín,tí wọn fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ń ṣe iranṣẹ rẹ̀,gbogbo àwọn tí ó bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, tí kò sọ ọ́ di ohun ìríra,tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,

7. n óo mú wọn wá sí orí òkè mímọ́ mi,n óo jẹ́ kí inú wọn máa dùn ninu ilé adura mi.Ọrẹ sísun ati ẹbọ wọn, yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi;nítorí ilé adura fún gbogbo eniyan, ni a óo máa pe ilé mi.”

8. OLUWA Ọlọrun tí ń kó àwọn tí ogun túká ní Israẹli jọ sọ pé,“N óo tún kó àwọn mìíràn jọ,kún àwọn tí mo ti kọ́ kó jọ.”

Ka pipe ipin Aisaya 56