Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 56:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní: “Ẹ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́,kí ẹ sì máa ṣe òdodo;nítorí ìgbàlà mi yóo dé láìpẹ́,ẹ óo sì rí ìdáǹdè mi.

2. Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀,ati fún ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé e,tí ó ń ṣọ́ra, tí kò rú òfin ọjọ́ ìsinmi,tí kò sì fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe nǹkan burúkú.”

3. Kí àjèjì tí ó faramọ́ OLUWA má sọ pé,“Dájúdájú OLUWA yóo yà mí kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.”Kí ìwẹ̀fà má sì sọ pé,“Wò ó! Mo dàbí igi gbígbẹ.”

Ka pipe ipin Aisaya 56