Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 54:12-17 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Òkúta Agate ni n óo fi ṣe ṣóńṣó ilé rẹ,òkúta dídán ni n óo fi ṣe ẹnu ọ̀nà ibodè rẹ,àwọn òkúta olówó iyebíye ni n óo fi mọ odi rẹ.

13. “Gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ni OLUWA yóo kọ́wọn yóo sì ṣe ọpọlọpọ àṣeyọrí.

14. A óo fìdí rẹ múlẹ̀, ninu òdodo,o óo jìnnà sí ìnira, nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà ọ́.O óo jìnnà sí ìpayà, nítorí kò ní súnmọ́ ọ.

15. Bí ẹnìkan bá dojú ìjà kọ ọ́, kìí ṣe èmi ni mo rán an,ẹnikẹ́ni tó bá gbéjà kò ọ́, yóo ṣubú nítorí rẹ.”

16. OLUWA ní,“Wò ó! Èmi ni mo dá alágbẹ̀dẹ,tí ó fi ẹwìrì fẹ́ná,tí ó sì rọ àwọn ohun ìjà, fún ìlò rẹ̀,èmi náà ni mo dá apanirun,pé kí ó máa panirun.

17. Kò sí ohun ìjà tí a ṣe láti fi bá ọ jàtí yóo lágbára lórí rẹ.Gbogbo ẹni tí ó bá bá ọ rojọ́ nílé ẹjọ́,ni o óo jàre wọn.Èyí ni ìpín àwọn iranṣẹ OLUWA,ati ìdáláre wọn lọ́dọ̀ mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Aisaya 54