Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 53:3-8 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀,wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀;ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́ tí ó sì mọ ìkáàánú ni.Ó dàbí ẹni tí àwọn eniyan ń wò ní àwòpajúdà.A kẹ́gàn rẹ̀, a kò sì kà á kún.

4. Nítòótọ́, ó ti gbé ìkáàánú wa lọ,ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa;sibẹsibẹ a kà á sí ẹni tí a nà,tí a sì jẹ níyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

5. Ṣugbọn wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìdára wa,wọ́n pa á lára nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa;ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni ó fún wa ní alaafia,nínà tí a nà án ni ó mú wa lára dá.

6. Gbogbo wa ti ṣáko lọ bí aguntan,olukuluku wa yà sí ọ̀nà tirẹ̀,OLUWA sì ti kó ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa lé e lórí.

7. Wọ́n ni í lára, wọ́n pọ́n ọn lójú,sibẹsibẹ kò lanu sọ̀rọ̀,wọ́n fà á lọ bí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń lọ pa,ati bí aguntan tíí yadi níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò lanu sọ̀rọ̀.

8. Wọ́n mú un lọ tipátipá,lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lẹ́jọ́,ta ni ninu ìran rẹ̀ tí ó ṣe akiyesi péwọ́n ti pa á run lórí ilẹ̀ alààyè,ati pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi, ni wọ́n ṣe nà án?

Ka pipe ipin Aisaya 53