Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 53:3-12 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀,wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀;ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́ tí ó sì mọ ìkáàánú ni.Ó dàbí ẹni tí àwọn eniyan ń wò ní àwòpajúdà.A kẹ́gàn rẹ̀, a kò sì kà á kún.

4. Nítòótọ́, ó ti gbé ìkáàánú wa lọ,ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa;sibẹsibẹ a kà á sí ẹni tí a nà,tí a sì jẹ níyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

5. Ṣugbọn wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìdára wa,wọ́n pa á lára nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa;ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni ó fún wa ní alaafia,nínà tí a nà án ni ó mú wa lára dá.

6. Gbogbo wa ti ṣáko lọ bí aguntan,olukuluku wa yà sí ọ̀nà tirẹ̀,OLUWA sì ti kó ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa lé e lórí.

7. Wọ́n ni í lára, wọ́n pọ́n ọn lójú,sibẹsibẹ kò lanu sọ̀rọ̀,wọ́n fà á lọ bí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń lọ pa,ati bí aguntan tíí yadi níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò lanu sọ̀rọ̀.

8. Wọ́n mú un lọ tipátipá,lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lẹ́jọ́,ta ni ninu ìran rẹ̀ tí ó ṣe akiyesi péwọ́n ti pa á run lórí ilẹ̀ alààyè,ati pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi, ni wọ́n ṣe nà án?

9. Wọ́n tẹ́ ẹ sí ibojì, pẹlu àwọn eniyan burúkú,wọ́n sì sin ín pẹlu ọlọ́rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ṣe ẹnikẹ́ni níbi,kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

10. Sibẹsibẹ, ó wu OLUWA láti pa á lára,ó sì fi í sinu ìbànújẹ́,nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;yóo fojú rí ọmọ rẹ̀,ọjọ́ rẹ̀ yóo sì gùn.Ìfẹ́ OLUWA yóo ṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀.

11. Yóo rí èrè àníyàn ọkàn rẹ̀,yóo sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi, olódodo,yóo dá ọpọlọpọ eniyan láre,yóo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

12. Nítorí náà, n óo fún un ní ìpín,láàrin àwọn eniyan ńlá,yóo sì bá àwọn alágbára pín ìkógun,nítorí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ikú,wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.Sibẹsibẹ ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan,ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 53