Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 52:9-15 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ẹ jọ máa kọrin pọ̀,gbogbo ilẹ̀ Jerusalẹmu tí a sọ di aṣálẹ̀,nítorí OLUWA yóo tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu,yóo ra Jerusalẹmu pada.

10. OLUWA yóo lo agbára mímọ́ rẹ̀, lójú àwọn orílẹ̀-èdè,gbogbo eniyan, títí dé òpin ayé, yóo sì rí ìgbàlà Ọlọrun wa.

11. Ẹ jáde, ẹ jáde ẹ kúrò níbẹ̀,ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan,ẹ jáde kúrò láàrin rẹ̀, kí ẹ sì wẹ ara yín mọ́,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò OLUWA.

12. Nítorí pé ẹ kò ní fi ìkánjú jáde,bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní sáré jáde.Nítorí OLUWA yóo máa lọ níwájú yín,Ọlọrun Israẹli yóo sì wà lẹ́yìn yín.

13. Wò ó! Iranṣẹ mi yóo ṣe àṣeyọría óo gbé e ga, a óo gbé e lékè;yóo sì di ẹni gíga,

14. Ẹnu ti ya ọpọlọpọ eniyan nítorí rẹ̀.Wọ́n bà á lójú jẹ́ yánnayànna,tóbẹ́ẹ̀ tí ìrísí rẹ̀ kò fi jọ ti eniyan mọ́.

15. Bẹ́ẹ̀ ni yóo di ohun ìyanu fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè,kẹ́kẹ́ yóo pamọ́ àwọn ọba wọn lẹ́nu,nígbà tí wọ́n bá rí i,wọn óo rí ohun tí wọn kò gbọ́ rí nípa rẹ̀,òye ohun tí wọn kò mọ̀ rí yóo yé wọn.

Ka pipe ipin Aisaya 52