Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 52:5-9 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ṣugbọn nisinsinyii, kí ni mo rí yìí? Wọ́n mú àwọn eniyan mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn alákòóso wọn ń pẹ̀gàn, orúkọ mi wá di nǹkan yẹ̀yẹ́?

6. Nítorí náà àwọn eniyan mi yóo mọ orúkọ mi, wọn óo sì mọ̀ ní ọjọ́ náà pé, èmi tí mò ń sọ̀rọ̀, èmi náà nìyí.”

7. Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìyìn rere bọ̀ ti dára tó lórí òkè,ẹni tí ń kéde alaafia,tí ń mú ìyìn rere bọ̀,tí sì ń kéde ìgbàlà,tí ń wí fún Sioni pé,“Ọlọrun rẹ jọba.”

8. Gbọ́, àwọn aṣọ́de rẹ gbóhùn sókè,gbogbo wọn jọ ń kọrin ayọ̀,nítorí wọ́n jọ fi ojú ara wọn rí i,tí OLUWA pada dé sí Sioni.

9. Ẹ jọ máa kọrin pọ̀,gbogbo ilẹ̀ Jerusalẹmu tí a sọ di aṣálẹ̀,nítorí OLUWA yóo tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu,yóo ra Jerusalẹmu pada.

Ka pipe ipin Aisaya 52