Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 52:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jí, Sioni, jí!Gbé agbára rẹ wọ̀ bí aṣọ,gbé ẹwà rẹ wọ̀ bí ẹ̀wù,ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́;nítorí àwọn aláìkọlà ati aláìmọ́, kò ní wọ inú rẹ mọ́.

2. Dìde, gbọnranù kúrò ninu erùpẹ̀,ìwọ Jerusalẹmu tí ó wà ninu ìdè.Tú okùn tí a dè mọ́ ọ lọ́rùn kúrò,ìwọ Sioni tí ó wà ninu ìdè.

3. Nítorí OLUWA ní, “Ọ̀fẹ́ ni a mu yín lẹ́rú, ọ̀fẹ́ náà sì ni a óo rà yín pada.

4. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn eniyan mi lọ ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Ijipti, lẹ́yìn náà, àwọn ará Asiria pọ́n wọn lójú láì nídìí.

5. Ṣugbọn nisinsinyii, kí ni mo rí yìí? Wọ́n mú àwọn eniyan mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn alákòóso wọn ń pẹ̀gàn, orúkọ mi wá di nǹkan yẹ̀yẹ́?

6. Nítorí náà àwọn eniyan mi yóo mọ orúkọ mi, wọn óo sì mọ̀ ní ọjọ́ náà pé, èmi tí mò ń sọ̀rọ̀, èmi náà nìyí.”

Ka pipe ipin Aisaya 52