Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 51:7-17 BIBELI MIMỌ (BM)

7. “Ẹ̀yin tí ẹ mọ òdodo, ẹ gbọ́ ohùn mi,ẹ̀yin tí ẹ fi tọkàntọkàn gba òfin mi,ẹ má bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn eniyan;ẹ má sì jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ wọn já a yín láyà.

8. Ikán yóo jẹ wọ́n bí aṣọ,kòkòrò yóo jẹ wọ́n bí òwú;ṣugbọn ìdáǹdè mi yóo wà títí lae,ìgbàlà mi yóo sì wà láti ìran dé ìran.”

9. Jí, jí! Dìde, OLUWA, jí pẹlu agbára;jí bí ìgbà àtijọ́,bí o ti ṣe sí ìran wa látijọ́.Ṣebí ìwọ ni o gé Rahabu wẹ́lẹwẹ̀lẹ,tí o fi idà gún diragoni?

10. Àbí ìwọ kọ́ ni o mú kí omi òkun gbẹ,omi inú ọ̀gbun ńlá;tí o sọ ilẹ̀ òkun di ọ̀nà,kí àwọn tí o rà pada lè kọjá?

11. Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada wá,pẹlu orin ni wọn óo pada wá sí Sioni.Adé ayọ̀ ni wọn óo dé sórí,wọn óo láyọ̀, inú wọn yóo dùn;ìbànújẹ́ ati ẹ̀dùn wọn yóo sì fò lọ.

12. “Èmi fúnra mi ni mò ń tù ọ́ ninu,ta ni ọ́, tí o fi ń bẹ̀rù eniyan tí yóo kú?Ìwọ ń bẹ̀rù ọmọ eniyan tí a dá, bíi koríko.

13. O gbàgbé OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ,tí ó ta ojú ọ̀run bí aṣọ,tí ó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀.O wá ń fi gbogbo ọjọ́ ayé bẹ̀rù ibinu àwọn aninilára,nítorí wọ́n múra tán láti pa ọ́ run?Ibinu àwọn aninilára kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ mọ́.

14. Láìpẹ́, a óo tú àwọn tí a tẹ̀ lórí ba sílẹ̀.Wọn kò ní kú, wọn kò ní wọ inú isà òkú,wọn kò sì ní wá oúnjẹ tì.

15. “Nítorí èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ,ẹni tí ó rú òkun sókè,tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo;OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ mi.

16. Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu,mo ti pa ọ́ mọ́ lábẹ́ òjìji ọwọ́ mi.Èmi ni mo fi ojú ọ̀run sí ipò rẹ̀,tí mo fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,tí mo sì sọ fún ìlú Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni eniyan mi.’ ”

17. Jí, jí! Dìde, ìwọ Jerusalẹmu.Ìwọ tí o ti rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibinu OLUWA,ìwọ tí OLUWA ti fi ibinu jẹ níyà,tí ojú rẹ wá ń pòòyì.

Ka pipe ipin Aisaya 51