Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 51:15-23 BIBELI MIMỌ (BM)

15. “Nítorí èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ,ẹni tí ó rú òkun sókè,tí ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo;OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ mi.

16. Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu,mo ti pa ọ́ mọ́ lábẹ́ òjìji ọwọ́ mi.Èmi ni mo fi ojú ọ̀run sí ipò rẹ̀,tí mo fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,tí mo sì sọ fún ìlú Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni eniyan mi.’ ”

17. Jí, jí! Dìde, ìwọ Jerusalẹmu.Ìwọ tí o ti rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibinu OLUWA,ìwọ tí OLUWA ti fi ibinu jẹ níyà,tí ojú rẹ wá ń pòòyì.

18. Kò sí ẹni tí yóo tọ́ ọ sọ́nà,ninu gbogbo àwọn ọmọ tí o ti bí,kò sí ẹni tí yóo fà ọ́ lọ́wọ́,ninu gbogbo ọmọ tí o tọ́ dàgbà.

19. Àjálù meji ló dé bá ọ,ta ni yóo tù ọ́ ninu:Ìsọdahoro ati ìparun, ìyàn ati ogun,ta ni yóo tù ọ́ ninu?

20. Àárẹ̀ mú àwọn ọmọ rẹ,wọ́n sùn káàkiri ní gbogbo òpópó,bí ìgalà tí ó bọ́ sinu àwọ̀n.Ibinu OLUWA rọ̀jò lé wọn lórí,àní ìbáwí Ọlọrun rẹ.

21. Nítorí náà, ẹ̀yin tí à ń fi ìyà jẹ, ẹ gbọ́ èyí;ẹ̀yin tí ẹ ti yó láì tíì mu ọtí,

22. Oluwa rẹ, àní OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ní,“Wò ó! Mo ti gba ife àmutagbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n lọ́wọ́ rẹ,O kò ní rí ibinu mi mọ́.

23. Àwọn tí ń dá ọ lóró ni yóo rí ibinu mi,àwọn tí ó wí fún ọ pé,‘Bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí á gba orí rẹ kọjá;’tí wọ́n sọ ẹ̀yìn rẹ di ilẹ̀ẹ́lẹ̀,tí wọ́n sọ ọ́ di ojú ọ̀nà wọn, tí wọn óo máa gbà kọjá.”

Ka pipe ipin Aisaya 51