Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 50:7-11 BIBELI MIMỌ (BM)

7. OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́,nítorí náà ojú kò tì mí;nítorí náà mo múra gírí,mo jẹ́ kí ojú mi le koko,mo sì mọ̀ pé ojú kò ní tì mí.

8. Ẹni tí yóo dá mi láre wà nítòsí,ta ló fẹ́ bá mi jà?Ta ló fẹ́ fi ẹ̀sùn kàn mí?Kí olúwarẹ̀ súnmọ́ tòsí mi,kí á jọ kojú ara wa?

9. Wò ó! OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́,ta ni yóo dá mi lẹ́bi?Gbogbo wọn ni yóo gbọ̀n dànù bí aṣọ,kòkòrò yóo sì jẹ wọ́n.

10. Ta ló bẹ̀rù OLUWA ninu yín,tí ń gbọ́ràn sí iranṣẹ rẹ̀ lẹ́nu,tí ń rìn ninu òkùnkùn,tí kò ní ìmọ́lẹ̀,ṣugbọn sibẹ, tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,tí ó fẹ̀yìn ti Ọlọrun rẹ̀.

11. Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dáná,tí ẹ tan iná yí ara yín ká,ẹ máa rìn lọ ninu iná tí ẹ dá;ẹ máa la iná tí ẹ fi yí ara yín ká kọjá.Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fun yín.Ẹ óo wà ninu ìrora.

Ka pipe ipin Aisaya 50