Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 5:9-14 BIBELI MIMỌ (BM)

9. OLUWA ọmọ ogun ti búra lójú mi, ó ní,“Láìsí àní-àní, ọpọlọpọ ilé ni yóo di ahoro,ọ̀pọ̀ ilé ńláńlá, ati ilé dáradára yóo sì wà láìsí olùgbé.

10. Apẹ̀rẹ̀ èso àjàrà kan ni a óo rí ká ninu ọgbà àjàrà sarè mẹ́wàá.Kóńgò èso kan ni ẹni tí ó gbin kóńgò marun-un yóo rí ká.”

11. Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n jí ní òwúrọ̀ kutukutu,láti máa wá ọtí líle kiri,tí wọ́n ń mu ún títí di ìrọ̀lẹ́,títí tí ọtí yóo fi máa pa wọ́n!

12. Dùùrù, hapu, ìlù, fèrè ati ọtí waini wà níbi àsè wọn;ṣugbọn wọn kì í bìkítà fún iṣẹ́ Ọlọrun,wọn kìí sìí náání iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

13. Nítorí náà àwọn eniyan mi óo lọ sí oko ẹrú nítorí àìmòye wọn,ebi ni yóo pa àwọn ọlọ́lá wọn ní àpakú,òùngbẹ óo sì gbẹ ọpọlọpọ wọn.

14. Isà òkú ti ṣetán, yóo gbé wọn mì,ó ti yanu kalẹ̀.Àwọn ọlọ́lá Jerusalẹmu yóo já sinu rẹ́,ati ọ̀pọ̀ ninu àwọn ará ìlú,ati àwọn tí ń fi ìlú Jerusalẹmu yangàn.

Ka pipe ipin Aisaya 5