Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 5:13-22 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Nítorí náà àwọn eniyan mi óo lọ sí oko ẹrú nítorí àìmòye wọn,ebi ni yóo pa àwọn ọlọ́lá wọn ní àpakú,òùngbẹ óo sì gbẹ ọpọlọpọ wọn.

14. Isà òkú ti ṣetán, yóo gbé wọn mì,ó ti yanu kalẹ̀.Àwọn ọlọ́lá Jerusalẹmu yóo já sinu rẹ́,ati ọ̀pọ̀ ninu àwọn ará ìlú,ati àwọn tí ń fi ìlú Jerusalẹmu yangàn.

15. A tẹ eniyan lórí ba,a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ojú àwọn onigbeeraga yóo sì wálẹ̀.

16. Ṣugbọn OLUWA àwọn ọmọ ogunni a óo gbéga ninu ẹ̀tọ́ nítorí ìdájọ́ òdodoỌlọrun Mímọ́ yóo fi ara rẹ̀ hàn, pé mímọ́ ni òun ninu òdodo.

17. Nígbà náà ni àwọn ọ̀dọ́ aguntan yóo máa jẹ oko ninu pápá oko wọnàwọn àgbò ati ewúrẹ́ yóo sì máa jẹko ninu ahoro wọn.

18. Àwọn tí ń ṣe àfọwọ́fà ẹ̀ṣẹ̀ gbé!Àwọn tí wọn ń fi ìwà aiṣododo fa ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni tí ń fi okùn fa ẹṣin.

19. Tí wọn ń wí pé:“Kí ó tilẹ̀ ṣe kíá,kí ó ṣe ohun tí yóo ṣe, kí á rí i.Jẹ́ kí àbá Ẹni Mímọ́ Israẹli di òtítọ́kí ó ṣẹlẹ̀, kí á lè mọ̀ ọ́n!”

20. Àwọn tí ń pe ibi ní ire gbé;tí wọn ń pe ire ní ibi!Àwọn tí wọn ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀,tí wọn sì fi ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn!Tí wọ́n fi ìkorò ṣe adùn,tí wọ́n sì fi adùn ṣe ìkorò.

21. Àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn gbé;tí wọ́n ka ara wọn kún ẹni tí ó ní ìmọ̀!

22. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá ninu ọtí mímu gbé;tí wọ́n jẹ́ akikanjubí ó bá di pé kí á da ọtí líle pọ̀ mọ́ ara wọn!

Ka pipe ipin Aisaya 5